Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 3:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ wọ̀n-un-nì, Jòhánù onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní ihà Jùdíà.

2. Ó ń wí pé, “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run dé tán.”

3. Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé:“Ohùn ẹnìkan ti ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

4. Irun ràkúnmí ni a fi hun aṣọ Jòhánù, awọ ni ó sì fi di àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

5. Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerúsálémù àti gbogbo Jùdíà àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jọ́dánì.

6. Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó ṣe í ìtẹ̀bọmi fún wọn nínú odò Jọ́dánì ibi tí ó ti ń se.

7. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisí àti Sadúsì tí wọ́n ń wá si ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ibínú Ọlọ́run tí ń bọ̀?

Ka pipe ipin Mátíù 3