Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:51-64 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

51. Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì ṣá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.

52. Jésù wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni.

53. Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) ańgẹ́lì méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹsẹ̀kẹsẹ̀.

54. Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsìn yìí?”

55. Nígbà náà ni Jésù wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Tàbí èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹ̀ḿpìlì, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.

56. Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan-an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sá lọ.

57. Àwọn tí ó mú Jésù fà á lọ sí ilé Káíáfà, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olúkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbààgbà Júù péjọ sí.

58. Ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jésù.

59. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé-ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù pé jọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jésù, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un.

60. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde.

61. Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘èmi lágbára láti wó tẹ̀ḿpìlì Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”

62. Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jésù pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?”

63. Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́ rọ́rọ́.Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run.”

64. Jésù sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí,” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ-Ènìyàn ti yóò jókóó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùukù.”

Ka pipe ipin Mátíù 26