Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 26:39-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeé se, jẹ́ kí a mú aago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

40. Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Pétérù, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?

41. Ẹ kún fún ìṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹ́wò. Nítorí Ẹ̀mi ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”

42. Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí aago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá àfi tí mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”

43. Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun.

44. Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.

45. Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó sánmọ̀ wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

46. Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

47. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá àti àgbààgbà Júù wá.

48. Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.”

Ka pipe ipin Mátíù 26