Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 25:24-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé oǹrorò enìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kó jọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí.

25. Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ńtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’

26. “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kó jọ níbi tí èmi kò ó ká sí.

27. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.

28. “ ‘Ó sì páṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá.

29. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní.

30. Nítorí ìdi èyí, gbé aláìlérè ọmọ-ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ niẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’

31. “Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ-Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run.

32. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kó jọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́.

33. Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì.

34. “Nígbà náà ni Ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé.

Ka pipe ipin Mátíù 25