Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 25:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé àtùpa wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó.

2. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọgbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n.

3. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé àtùpà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́.

4. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó dání pẹ̀lú àtùpà wọn.

5. Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.

6. “Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’

7. “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún àtùpà wọn ṣe.

8. Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọgbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí àtùpà wọn ń kú lọ.

9. “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má baà ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.

10. “Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àṣè ìgbéyàwó, lẹ̀yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.

11. “Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘olúwa, olúwa, sílẹ̀kùn fún wa.’

12. “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’

13. “Nítorí náà, Ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ-Ènìyàn yóò dé.

Ka pipe ipin Mátíù 25