Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 24:24-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nítorí àwọn èké Kírísítì àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.

25. Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.

26. “Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní ihà,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́.

27. Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-òòrùn títí dé ìwọ̀-oòrun, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn yóò jẹ́.

28. Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọ pọ̀ sí.

29. “Lójú kan náà lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,“ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn,òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn;àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀,agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’

30. “Nígbà náà ni àmì Ọmọ-Ènìyàn yóò si fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ-Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.

31. Yóò sì rán àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ.

32. “Nísinsìn yìí, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ titun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́ tòòsí,

33. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadabọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

34. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.

35. Ọ̀run àti ayé yóò ré kọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò ré kọjá.

36. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn ańgẹ́lì pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ Ọlọ́run kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.

37. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Nóà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn yóò sì rí.

38. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Nóà fi bọ́ sínú ọkọ̀.

39. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ-Ènìyàn.

40. Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa ṣiṣẹ́ nínú oko, a yóò mú ẹnì kan, a ó sì fi ẹnì kejì sílẹ̀.

41. Àwọn obìnrin méjì yóò jùmọ̀ máa lọ ọlọ́ pọ̀, a yóò mú ọ̀kan, a ó fi ẹnì kejì sílẹ̀.

Ka pipe ipin Mátíù 24