Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 23:7-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Ráábì.’

8. “Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Ráábì, nítorí pé ẹnì kan ni Olùkọ́ yín, àní Kírísítì, ará sì ni gbogbo yín.

9. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

10. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kírísítì.

11. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀ jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín.

12. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbé ga.

13. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ẹ́ wọlé ó wọlé.

14. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bí púpọ̀.

15. “Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti òkun ká láti yí ẹnì kan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá.

16. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afójú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹ́ḿpílì búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹ́ḿpílì búra, ó di ajigbèsè.’

17. Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú: èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹ́ḿpílì tí ó ń sọ wúrà di mímọ́?

18. Àti pé, Ẹmikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò já mọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè.

19. Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀ jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnra rẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́?

20. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀.

Ka pipe ipin Mátíù 23