Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 22:3-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti lọ sọ fún àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ pé àsìkò ti tó láti wá sí ibi àsè. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn kọ̀ láti wá.

4. “Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti se àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyáwó.’

5. “Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kán á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.”

6. Àwọn ìyókù sì lu àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ta àbùkù fún wọn, wọ́n lù wọ́n pa.

7. Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn

8. “Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà.

9. Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’

10. Nítorí náà, àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àṣè ìyàwó sì kún fún àlejò.

11. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ àṣọ ìgbéyàwó.

12. Ọba sì bi í pé, ‘Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láì ní aṣọ ìgbéyàwó?’ Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan.

13. “Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà.’

14. “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”

15. Nígbà náà ni àwọn Farisí pé jọ pọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un.

16. Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hérọ́dù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olótìítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

17. Nísinsìn yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó-orí fún Késárì tàbí kò tọ́?”

18. Ṣùgbọ́n Jésù ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, è é se ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò?

19. Ẹ fi owo ẹyọ tí a fi ń san owo-orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,

20. ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán tabi èyí? Àkọlé tà sì ní?”

21. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Késárì ni.”“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Késárì fún Késárì, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

22. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnú yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

23. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jésù wá láti bi í ní ìbéèrè pé,

Ka pipe ipin Mátíù 22