Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 20:30-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

31. Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i. “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

32. Jésù dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n pé, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”

Ka pipe ipin Mátíù 20