Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 20:14-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó ní, Gba èyí tíí ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ.

15. Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’

16. “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”

17. Bí Jésù ti ń gòkè lọ sí Jerúsálémù, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé,

18. “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú.

19. Wọn yóò sì lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”

20. Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sébédè bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojú rere rẹ̀.

21. Jésù béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”

22. Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú aago tí èmi ó mu?”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”

23. Jésù sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú aago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jòkòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè àyè wọ́n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”

24. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàà ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí.

25. Ṣùgbọ́n Jésù pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrin wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba.

26. Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrin yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrin yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni,

27. Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe Ọmọ-ọ̀dọ̀ yin.

28. Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

29. Bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jẹ́ríkò sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn.

30. Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

31. Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i. “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”

32. Jésù dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n pé, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”

33. Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”

34. Àánú wọn sì ṣe Jésù, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójú kan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Ka pipe ipin Mátíù 20