Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 2:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ẹrù wọn, wọ́n sì ta Jésù lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjíà.

12. Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Hérọ́dù lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.

13. Nígbà tí wọn ti lọ, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sá lọ sí Éjíbítì. Dúró níbẹ̀ títítí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Hẹ́rọ̀dù yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ-ọwọ́ náà.”

14. Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Éjíbítì,

15. ó sì wà níbẹ̀ títítí Hẹ́rọ́dù fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Éjíbítì wá.”

16. Nígbà tí Hẹ́rọ̀dù rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.

17. Nígbà náà ni èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeriemáyà wá sẹ pé:

18. “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà,Ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńláRákélì ń sọkùn àwọn ọmọ rẹ̀Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.”

19. Lẹ́yìn ikú Hẹ́rọ́dù, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù lójú àlá ní Éjíbítì

20. Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn tí ń wá ọmọ-ọwọ́ náà láti pa ti kú.”

21. Nítorí náà, Ó sì dìde, ó gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Ákílọ́sì ni ó ń jọba ní Jùdíà ní ipò Hẹ́rọ́dù baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Gálílì lọ,

23. ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Násárẹ́tì. Nígbà náà ni èyí tí a sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Násárẹ́tì.”

Ka pipe ipin Mátíù 2