Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 19:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ó sì wí fún un pé, Nítorí ìdí èyí ‘Ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sí da ara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì náà á sì di ara kan.’

6. Wọn kì í tún ṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”

7. Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mósè fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀?”

8. Jésù dáhùn pé, “Mósè yọ̀ǹda kí ẹ kọ aya yín sílẹ̀ nítorí ọkàn yín le. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ láti àtètèkọ́ṣe.

9. Mo sọ èyí fún yín pé, ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó sì fẹ́ òmíràn, ó ṣe panṣágà.”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrin ọkọ àti aya, kó ṣààfààní fún wa láti gbé ìyàwó.”

11. Jésù dáhùn pé, “Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún.

12. Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ nía bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.”

13. Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14. Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.”

15. Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

16. Ẹnì kan sì wá ó bí Jésù pé, “Olùkọ́, ohun rere wo ni èmi yóò ṣe kí n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17. Jésù dá a lóhùn pé, “È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

Ka pipe ipin Mátíù 19