Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 19:15-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

16. Ẹnì kan sì wá ó bí Jésù pé, “Olùkọ́, ohun rere wo ni èmi yóò ṣe kí n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17. Jésù dá a lóhùn pé, “È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

18. Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jésù dáhùn pé, “ ‘Má ṣe pànìyàn, má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe ìjẹ̀rìí èké,

19. bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20. Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe?”

21. Jésù wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23. Nígbà náà, ní Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.”

24. Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”

25. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”

26. Jésù sì tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Bí o bá jẹ́ ti ènìyàn ni, eléyìí sòro. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ti Ọlọ́run ni, ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

Ka pipe ipin Mátíù 19