Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 19:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Lẹ́yìn náà a sì gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14. Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun, nítorí irú wọn ni ìjọba ọ̀run.”

15. Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

16. Ẹnì kan sì wá ó bí Jésù pé, “Olùkọ́, ohun rere wo ni èmi yóò ṣe kí n tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17. Jésù dá a lóhùn pé, “È é ṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

18. Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jésù dáhùn pé, “ ‘Má ṣe pànìyàn, má ṣe ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe ìjẹ̀rìí èké,

19. bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. Kí o sì fẹ́ aládúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20. Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi mo ní láti ṣe?”

21. Jésù wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23. Nígbà náà, ní Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.”

Ka pipe ipin Mátíù 19