Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 18:19-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín.

20. Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrin wọn níbẹ̀.”

21. Nígbà náà ni Pétérù wá sọ́dọ̀ Jésù, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”

22. Jésù dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í se ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje;

23. “Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ se ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀.

24. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbésè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàáárún (10,000) talẹ́ńtì.

25. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.

26. “Nígbà náà ni ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’

27. Nígbà náà, ni olúwa ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbésè náà jì í.

28. “Ṣùgbọ́n bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún dínárì, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé ‘san gbéṣè tí o jẹ mí lójú ẹṣẹ̀.’

29. “Arákùnrin náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’

30. “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbésè náà tán pátápátá.

31. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó sẹlẹ̀.

32. “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ Ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbésè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi;.

Ka pipe ipin Mátíù 18