Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:28-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Jésù sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá ní wákàtí kan náà.

29. Jésù ti ibẹ̀ lọ sí òkun Gálílì. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀.

30. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúkùn-ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jésù. Òun sì mú gbogbo wọn lárada.

31. Ẹnú ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúkùn-ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

32. Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”

33. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ihà níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”

34. Jésù sì béèrè pé, “ìsù Búrẹ́dì mélòó ni ẹ̀yín ní?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìsù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”

35. Jésù sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.

36. Òun sì mú ìsù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà.

Ka pipe ipin Mátíù 15