Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:23-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn, Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á nìyànjú pé, “lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24. Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí ó nù nìkan ni a rán mi sí”

25. Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26. Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

27. Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èérún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.”

28. Jésù sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá ní wákàtí kan náà.

29. Jésù ti ibẹ̀ lọ sí òkun Gálílì. Ó gun orí òkè, o sì jókòó níbẹ̀.

30. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúkùn-ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jésù. Òun sì mú gbogbo wọn lárada.

31. Ẹnú ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúkùn-ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

32. Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”

Ka pipe ipin Mátíù 15