Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 14:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, ọmọ Hẹ́rọ́díà obìnrin jó dáadáa, ó sì tẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ́run gidigidi.

7. Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.

8. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú àwo pọ̀kọ́”.

9. Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀jẹ́ rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.

10. Nítorí náà, a bẹ́ orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú.

11. A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwo pọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé etọ ìyá rẹ̀ lọ.

12. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jésù.

13. Nígbà tí Jésù gbọ́ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kúrò níbẹ̀, ó bá ọkọ̀ ojú-omi lọ sí ibi kọ́lọ́fin kan ní èbúté láti dá wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn si fi ẹṣẹ̀ rìn tẹ̀lé e láti ọ̀pọ̀ ìlú wọn.

14. Nígbà ti Jésù gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ò sì mú àwọn aláìsàn láradá.

15. Nígbà ti ilẹ̀ ń sú lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé, “Ibi yìí jìnnà sí ìlú ilẹ̀ sì ń ṣú lọ. Rán àwọn ènìyàn lọ sí àwọn ìletò kí wọ́n lè ra oúnjẹ jẹ.”

16. Ṣùgbọ́n Jésù fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

17. Wọ́n sì da lóhùn pé, “Àwá kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.”

18. Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.”

19. Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-un àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.

20. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.

Ka pipe ipin Mátíù 14