Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 14:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Lójú kan náà, Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

28. Pétérù sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”

29. Jésù dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”Nígbà náà ni Pétérù sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jésù.

30. Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”

Ka pipe ipin Mátíù 14