Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 14:25-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ní déédé agogo mẹ́rin òwúrọ̀, Jésù tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi.

26. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.

27. Lójú kan náà, Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”

28. Pétérù sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”

29. Jésù dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”Nígbà náà ni Pétérù sọ̀ kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jésù.

30. Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”

31. Lójú kan náà, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó dì í mú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èé ṣe tí ìwọ fi ṣiyè méjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”

32. Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́.

33. Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà forí balẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”

34. Nígbà tí wọn ré kọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Gẹ́nẹ́sárẹ́tì.

35. Nígbà ti wọn mọ̀ pé Jésù ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá.

36. Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

Ka pipe ipin Mátíù 14