Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 12:39-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Ó sì dá wọn lóhùn wí pé “Ìran búburú àti ìran panságà ń béèrè àmì; ṣùgbọ́n kò sí àmí tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì.

40. Bí Jónà ti gbé inú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn yóò gbé ní inú ilẹ̀ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.

41. Àwọn ará Nínéfè yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronú pìwàdà nípa ìwàásù Jónà. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Jónà wà níhìn-in yìí.

42. Ọbabìnrin gúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Sólóḿonì. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Sólómónì ń bẹ níhìn-ín yìí.

43. “Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní aṣálẹ̀, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i.

44. Nígbà náà ni ẹ̀mí yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́.

45. Nígbà náà ni ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà yóò wá ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ti ìṣáájú lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”

46. Bí Jésù ti ṣe ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wà lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀.

47. Nígbà náà ni ẹnì kan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”

48. Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?”

49. Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.”

50. Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

Ka pipe ipin Mátíù 12