Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 11:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Gálílì gbogbo.

2. Nígbà tí Jòhánù gbọ́ ohun tí Kírísítì ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

3. láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

4. Jésù dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Jòhánù ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí.

5. Àwọn afójú ń ríran, àwọn amúkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìyìn rere fún àwọn òtòsì.

6. Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”

7. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù ti lọ tán, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Jòhánù: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginijù? Iféfé tí afẹ́fẹ́ ń mi?

8. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba.

9. Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.”

10. Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ,ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

11. Lóòótọ̀ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀ jù ú lọ.

12. Láti ìgbà ọjọ́ Jòhánù onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di àfagbárawọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á.

13. Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó wí tẹ́lẹ̀ kí Jòhánù kí ó tó dé.

Ka pipe ipin Mátíù 11