Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 10:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbéríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú sínágọ́gù.

18. Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ ṣíwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà.

19. Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín,

20. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

Ka pipe ipin Mátíù 10