Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 7:6-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Jésù dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òótọ́ ni wòlíì Àìṣáyà ń sọ nígbà tí ó ń ṣe àpèjúwe yín, tó wí pé:“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún miṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.

7. Ìsìn wọn jẹ́ lásán,ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkì dá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

8. Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apákan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àà àwọn ènìyàn.”

9. Ó si wí fún wọn: “Ẹyin sáà mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ.

10. Mósè fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni?’

11. Ṣùgbọ́n ẹyin wá yí i po pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí a sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi èyí tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run.

12. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí iyá rẹ̀ mọ́.

13. Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti yín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”

14. Lẹ́yìn náà, Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín.

15. Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.

16. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”

17. Nígbà tí Jésù sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa.

18. Jésù béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́?

19. Ìdí ni wí pé, Ohunkóhun tí ó bá wọ inú láti ìta, kò wọ inú ọkàn rárá, ṣùgbọ́n ó kọjá sí ikùn.” (Nípa sísọ èyí, Jésù fi hàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)

20. Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọni di aláìmọ́.

21. Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà,

22. ọ̀kánjúwà, odì-yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀.

Ka pipe ipin Máàkù 7