Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:49-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. ṣùgbọ́n nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé ìwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lohún rara,

50. nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Emi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

51. Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi nínú ara wọn, ẹnú sì yà wọ́n.

52. Wọn kò sá à ronú iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.

Ka pipe ipin Máàkù 6