Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:48-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

48. Ó rí i wí pé àwọ́n ọmọ-ẹyin wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,

49. ṣùgbọ́n nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé ìwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lohún rara,

50. nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Emi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

51. Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi nínú ara wọn, ẹnú sì yà wọ́n.

52. Wọn kò sá à ronú iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.

53. Lẹ́yìn tí wọ́n la òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Génésárétì. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté.

54. Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jésù, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n.

55. Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn wá pàdé rẹ̀.

56. Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ńṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárin ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.

Ka pipe ipin Máàkù 6