Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:35-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Nígbà tí ọjọ́ sì ti bu lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ ọ́ wa, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán.

36. “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”

37. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Eyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ lébìrà osù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra búrẹ́dì fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”

38. Jésù tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn ún àti ẹja méjì.”

39. Nígbà náà ni Jésù sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹẹgbẹ́ lórí koríko.

40. Lẹ́sẹ̀kan-náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọgọọ́rùn-ún.

41. Nígbà tí ó sì mú ìsù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ ṣíwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn.

42. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó.

43. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú.

44. Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5000) ọkùnrin.

45. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Bẹtisáídà. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn.

46. Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.

47. Nígbà tí ó dalẹ́, ọkọ̀ wà láàrin òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀.

48. Ó rí i wí pé àwọ́n ọmọ-ẹyin wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá,

49. ṣùgbọ́n nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé ìwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lohún rara,

50. nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Emi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

51. Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi nínú ara wọn, ẹnú sì yà wọ́n.

52. Wọn kò sá à ronú iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.

Ka pipe ipin Máàkù 6