Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 4:23-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

24. Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ maá kíyèsí ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n náà ni a ó fi wọ̀n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.

25. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún síi àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ń, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”

26. Ó sì tún ọ èyí pé, “Èyí ni a lè fí ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀.

27. Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìdè, irúgbìn náà hù jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀.

28. Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ni orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó.

29. Nígbà tí èṣo bá gbó tan, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòje bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”

30. Jésù sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀?

31. Ó dàbí èso hóró Músítádì kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan níńu àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbin sínú ilẹ̀.

32. Ṣíbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà sókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgba yókù lọ. Ó sì ya ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbò-bò.”

33. Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó.

Ka pipe ipin Máàkù 4