Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 3:16-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn, Ṣímóní (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Pétérù)

17. Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jésù sọ àpèlé wọ́n ní Bóánájì, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).

18. Àti Ańdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tómásì, Jákọ́bù (ọmọ Álíféù), Tádéù, Símónì (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó fẹ́ ará Kénánì tí ó fi ìjàngbọ̀n dojú ìjọba Rómù bolẹ̀)

19. Àti Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

20. Nígbà náà ni Jésù sì wọ inú ilé kan, àwọn ẹ̀rọ̀sì tún kórájọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn Ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun.

21. Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mu un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

22. Àwọn olùkọ́ni-ni-òfin ṣọkàlẹ̀ wá láti Jérúsálẹ́mù, wọn sì wí pé, “Ó ni Béélísébúbù, olórí àwọn ẹ̀mí Èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”

23. Jésù pè wọ́n, ó sì fi òwé bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èsù ṣe lè lé èsù jáde?

24. Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀.

25. Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò leè dúró.

26. Bí Èṣù bá sì díde sí ara rẹ, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé.

27. Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní erù lọ, bí kò se pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀.

28. Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dárí jin àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀ òdì.

29. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú èwù ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”

30. Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí Èṣù ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”

31. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dé. Wọ́n dúró lóde, wọ́n sì rán ẹnìkan sí i pé kí ó pè é wá.

32. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”

Ka pipe ipin Máàkù 3