Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 12:34-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Jésù rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jésù sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jésù.

35. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn Ọmọ-Ènìyàn nínú tẹ́ḿpílì, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “È é ṣe tí àwọn olùkọ́-òfin fi gbà wí pé Kírísítì náà ní láti jẹ́ ọmọ Dáfídì?

36. Nítorí tí Dáfídì tìkárarẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé:“ ‘Ọlọ́run sọ fún Olúwa mi:“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdi àpótí ìtìṣẹ̀ rẹ.” ’

37. Níwọ̀n ìgbà tí Dáfídì tìkáraarẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó tún ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

38. Ó sì wí fún wọn pé nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ́ra lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́-òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígun rìn kiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọja,

39. àti ibùjókòó ọlá nínú Sínágọ́gù àti ipò ọlá níbi àṣẹ.

40. Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígun fún àsehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”

41. Jésù jókòó kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.

42. Ṣùgbọn obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ kọ́bọ̀ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdáméjì owó-bàbà kan sínú rẹ̀.

43. Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìì sọ sínú àpótí ìsura ju gbogbo àwọn ìyókù lọ to sọ sínú rẹ lọ.

44. Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”

Ka pipe ipin Máàkù 12