Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 12:24-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ìṣòro yín ni wí pé, ẹ kò mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti agbára Ọlọ́run.

25. Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn ańgẹ́lì.

26. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Ẹ́kísódù, nípa Mósè àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mósè pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.’

27. Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”

28. Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jésù ti dáhùn dáadáa. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jésù pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”

29. Jésù dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ ọ̀kan náà, Ọlọ́run kan náà sì ni.

30. Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’

31. Èkejì ni pé: ‘Fẹ ọmọnikejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”

32. Olùkọ́ ófin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan.

33. Àti pé, mo mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo agbára mi, àti pẹ̀lú pé kí n fẹ́ràn ọmọnìkéjì mi gẹ́gẹ́ bí ara mi, ju kí n rú oríṣiiríṣii ẹbọ lórí i pẹpẹ ilé ìsìn.”

34. Jésù rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jésù sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jésù.

35. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn Ọmọ-Ènìyàn nínú tẹ́ḿpílì, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “È é ṣe tí àwọn olùkọ́-òfin fi gbà wí pé Kírísítì náà ní láti jẹ́ ọmọ Dáfídì?

36. Nítorí tí Dáfídì tìkárarẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé:“ ‘Ọlọ́run sọ fún Olúwa mi:“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdi àpótí ìtìṣẹ̀ rẹ.” ’

37. Níwọ̀n ìgbà tí Dáfídì tìkáraarẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó tún ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

38. Ó sì wí fún wọn pé nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ́ra lọ́dọ̀ àwọn olùkọ́-òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígun rìn kiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọja,

39. àti ibùjókòó ọlá nínú Sínágọ́gù àti ipò ọlá níbi àṣẹ.

40. Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígun fún àsehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”

41. Jésù jókòó kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.

Ka pipe ipin Máàkù 12