Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 1:29-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n lọ pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù sí ilé Símónì àti Ańdérù.

30. Ìyá ìyàwó Símónì tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jésù nípa rẹ̀.

31. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójú kan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

32. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí òòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá.

33. Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà.

34. Jésù sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú aláìsàn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í se.

35. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jésù nìkan jáde lọ sí ihà kan, láti lọ gbàdúrà.

36. Símónì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.

37. nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”

38. Jésù sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”

39. Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbégbé Gálílì, ó ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.

40. Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradà. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.”

41. Jésù kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.”

42. Lójúkan-náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.

43. Jésù sì kìlọ̀ fún un gidigidi

44. Ó wí pé, “Lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà Júù fún àyẹ̀wò. Ṣùgbọ́n má ṣe dúró sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà. Mú ẹ̀bùn lọ́wọ́, èyí tí Mósè pa láṣẹ fún adẹ́tẹ̀ tí a múláradá. Èyí tí í ṣe ẹ̀rí pé, ó ti rí ìwòsàn.”

45. Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkì, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀. Nítorí èyí, Jésù kò sì le wọ ìlú ní gba-n-gba mọ́, ṣùgbọ́n ó wà lẹ́yìn odi ìlú ní ihà. Ṣíbẹ̀, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.

Ka pipe ipin Máàkù 1