Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 1:10-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọkalẹ̀ lé E lórí.

11. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ìwọ ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

12. Lẹ́sẹ̀kan-náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jésù sí ihà,

13. Ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́. A sì fi Í lé Èṣù lọ́wọ́ láti dán an wò. Àwọn ańgẹ́lì sì wá ṣe ìtọ́jú Rẹ̀.

14. Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Hẹ́rọ́dù ti fi Jòhánù sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run.

15. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè. Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”

16. Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n.

17. Jésù sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

18. Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.

19. Bí Ó sì ti rìn ṣíwájú díẹ̀, ní etí òkun, Ó rí Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè nínú ọkọ̀ wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe.

20. Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀lé e.

21. Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapanámù, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsimi, ó lọ sínú sínágọ́gù, ó sì ń kọ́ni.

22. Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kóni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn.

23. Ní àsìkò náà gan-an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé,

24. “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jésù ti Násárẹ́tì? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”

25. Jésù si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúro lára rẹ̀.”

26. Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e sánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.

Ka pipe ipin Máàkù 1