21. Ó sì kìlọ̀ fún wọn, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.
22. Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ijọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”
23. Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti má a tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
24. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là
25. Nítorí pé èrè kínni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó ṣòfò.
26. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn ańgẹ́lì mímọ́.
27. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìnín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”
28. Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ijọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.
29. Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbò,
30. Sì kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì, Mósè àti Èlíjà, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀:
31. Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerúsálémù.
32. Ṣùgbọ́n ojú Pétérù àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró.