Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 9:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa apẹ̀rẹ̀ méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù fún wọn.

18. Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi èmi pè?”

19. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Èlíjà ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”

20. Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n tani ẹ̀yin ń fi èmi pè?”Pétérù sì dáhùn, wí pe, “Kírísítì ti Ọlọ́run.”

21. Ó sì kìlọ̀ fún wọn, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.

22. Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ijọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”

23. Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti má a tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.

24. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là

25. Nítorí pé èrè kínni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó ṣòfò.

26. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn ańgẹ́lì mímọ́.

27. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìnín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”

28. Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ijọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.

Ka pipe ipin Lúùkù 9