Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 8:8-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọrọrún.”Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó náhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”

9. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?”

10. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rírí,“ ‘kí wọn má baà rí,àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’

11. “Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

12. Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni Èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.

13. Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sáà díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.

14. Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó.

15. Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.

16. “Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àketè; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀.

17. Nítorí kò sí ohun tí ó farasin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba.

18. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin má a kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣebí òun ní.”

19. Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.

20. Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn fẹ́ rí ọ.”

21. Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”

22. Ní ijọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú-omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ lọ.

23. Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; wọ́n sì kún fún omi, wọ́n sì wà nínú ewu.

24. Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò sègbé!”Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé.

Ka pipe ipin Lúùkù 8