Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 8:41-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jáírù, ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bá ẹṣẹ̀ Jésù, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun:

42. Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ó ń kú lọ.Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ń há a ní àyè.

43. Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, (tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn), tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un lára dá,

44. Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.

45. Jésù sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?”Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Pétérù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn há ọ ní ààyè, wọ́n sì ń bì lù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”

46. Jésù sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”

47. Nígbà tí Obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò farasin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà.

48. Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, tújúká: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá; máa lọ ní àlààáfíà!”

49. Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí sínágọ́gù wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”

50. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”

51. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Pétérù, àti Jákọ́bù, àti Jòhánù, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà.

52. Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”

53. Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú.

54. Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!”

55. Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ.

56. Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.

Ka pipe ipin Lúùkù 8