Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 7:41-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.

42. Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríji àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, tani yóò fẹ́ ẹ jù?”

43. Símónì dáhùn wí pé, “Mo ṣebí ẹni tí ó dáríjìn jù ni.”Ó wí fún un pé, “O wí i re.”

44. Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Símónì pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹṣẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n òun, omije rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi n nù wọ́n nù.

45. Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́ṣẹ̀.

46. Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́ṣẹ̀.

47. Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”

Ka pipe ipin Lúùkù 7