Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 4:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Èsu sì mú un lọ sí Jerúsálémù, ó sì gbé e lé ṣóńṣo tẹ́ḿpílì, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí:

10. A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ,láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ: (fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pa ọ́ mọ́)

11. Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

12. Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

13. Nígbà tí Èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan.

14. Jésù sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Gálílì: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

15. Ó sì ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.

16. Ó sì wá sí Násárẹ́tì, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú sínágọ́gù lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé.

17. A sì fi ìwé wòlíì Àìsáyà fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:

18. “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,Nítorí tí ó fi àmì òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòsì.Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àtiìtúnríran fún àwọn afọ́jú,àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,

19. Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”

20. Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú sínágọ́gù sì tẹjúmọ́ ọn.

21. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónì-ín ìwé-Mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”

Ka pipe ipin Lúùkù 4