Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 4:35-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Jésù sì bá a wí gidigidi, ó ní, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.

36. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “ẹ̀kọ́ kínni èyi? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”

37. Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbégbé ilẹ̀ náà yíká.

38. Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú sínágọ́gù, ó sì wọ̀ ilé Símónì lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Símónì gúnlẹ̀; wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀.

39. Ó sì sunmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́: ó sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

40. Nígbà tí oòrun sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn mú àwọn aláìsàn tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá.

41. Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kírísítì náà.

42. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jésù sì jáde lọ ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má baà lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

43. Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàì má wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.”

44. Ó sì ń wàásù nínú sínágọ́gù ti Jùdíà.

Ka pipe ipin Lúùkù 4