Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 23:31-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kínni a ó ṣe sára gbígbẹ?”

32. Àwọn méjì mìíràn bákàn náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa.

33. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélèbú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì.

34. Jésù sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.

35. Àwọn ènìyàn sì dúró ń wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kírísítì, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”

36. Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un.

37. Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ́ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”

38. Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Gíríkì, àti ti Látínì, àti tí Hébérù: ÈYÍ NI ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

39. Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kírísítì, gba ara rẹ àti àwa là.”

40. Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?

41. Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwá ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

42. Ó sì wí pé, “Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ.”

Ka pipe ipin Lúùkù 23