63. Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jésù, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú.
64. Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?”
65. Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí I, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.
66. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọ pọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé,
67. “Bí ìwọ́ bá jẹ́ Kírísítì náà? Sọ fún wa!”Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́;
68. Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ).
69. Ṣùgbọ́n láti ìsinsinyìí lọ ni ọmọ-ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”