6. Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.
7. Ojọ́ àkàrà àìwú pé, nígbà tí wọ́n ní láti ṣe ìrúbọ ìrékọjá.
8. Ó sì rán Pétérù àti Jòhánù, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ”
9. Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
10. Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,
11. kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbọ̀ngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’
12. Òun ó sì fi gbọ̀ngàn ńlá kan lókè hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”
13. Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
14. Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn àpósítélì pẹ̀lú rẹ̀.
15. Ó sì wí fún wọn pé, “Tinú-tinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà:
16. Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”
17. Ó sì gba aago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrin ara yín.
18. Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”