Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 22:5-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mu láti fún un ní owó.

6. Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.

7. Ojọ́ àkàrà àìwú pé, nígbà tí wọ́n ní láti ṣe ìrúbọ ìrékọjá.

8. Ó sì rán Pétérù àti Jòhánù, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ”

9. Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”

10. Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,

11. kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbọ̀ngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’

12. Òun ó sì fi gbọ̀ngàn ńlá kan lókè hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”

13. Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.

14. Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn àpósítélì pẹ̀lú rẹ̀.

15. Ó sì wí fún wọn pé, “Tinú-tinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà:

16. Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”

17. Ó sì gba aago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrin ara yín.

18. Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”

19. Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fifún wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yí ni ara mí tí a fifún yín: ẹ má a ṣe èyí ní ìrántí mi.”

20. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú aago, ó wí pé, “Aago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.

21. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsí i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì.

22. Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.”

23. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn, tani nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.

24. Ìjà kan sì ń bẹ láàrin wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí níńu wọn.

Ka pipe ipin Lúùkù 22