Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 22:40-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwọ̀.”

41. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà.

42. Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, gba ago yìí lọ́wọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.”

43. Ańgẹ́lì kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú.

44. Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45. Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá ó bá wọn, wọ́n ń sùn fún ìbànújẹ́.

46. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹ́wò.”

47. Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Júdásì, ìkan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

48. Jesù sì wí fún un pé, “Júdásì, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?”

49. Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwá fi idà ṣá wọn?”

50. Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ-ẹ̀yìn olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.

51. Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀ báyìí ná.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn.

52. Jésù wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá?

53. Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójojúmọ́ ní tẹ́ḿpílì, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò ti yín ni èyí, àti agbára òkùnkùn.”

54. Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Pétérù tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè.

55. Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrin gbọ̀ngàn, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Pétérù jokòó láàrin wọn.

56. Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

Ka pipe ipin Lúùkù 22