Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 21:23-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fí ọmú fún ọmọ mu ní ijọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

24. Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dì wọ́n ní ìgbékùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerúsálémù yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.

25. “Àmì yóò sì wà ní ọ̀run, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpáyà híhó òkun àti ìgbì-omi.

26. Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì.

27. Nígbà náà ni wọn ó sì rí ọmọ-ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú ìkùukù àwọ̀sánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

28. Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

29. Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi;

30. Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnrarayín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́rẹ́fẹ́.

31. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o sẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.

32. “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.

33. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

34. “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.

35. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

36. Ǹjẹ́ kì ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ baà lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”

37. Lọ́sàn-án, a sì máa kọ́ni ní tẹ́ḿpílì: lóru, a sì máa jáde lọ wọ̀ lórí òkè tí à ń pè ní òkè Ólífì.

38. Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹ́ḿpílì ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 21