Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 21:12-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí sínágọ́gù, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.

13. Yóò sì padà di ẹ̀rí fún yín.

14. Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ lọ́kàn yín pé ẹ yóò ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn.

15. Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.

16. A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀ré; on ó sì mú kì a pa nínú yín.

17. A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.

18. Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé.

19. Nínú sùúrù yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.

20. “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerúsálémù ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀.

21. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdéà sá lọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrin rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbéríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá.

22. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ.

23. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fí ọmú fún ọmọ mu ní ijọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

Ka pipe ipin Lúùkù 21