Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 2:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Àwọn olùsọ́-àgùntàn ńbẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń sọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.

9. Ańgẹ́lì Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

10. Ańgẹ́lì náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìn rere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.

11. Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónì-ín ní ìlú Dáfídì, tí í ṣe Kírísítì Olúwa.

12. Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ-ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.

13. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ Ańgẹ́lì náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,

14. “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,Àti ní ayé àlààáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”

15. Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn ańgẹ́lì náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn Olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tàrà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀ jẹ, tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.”

16. Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọ-ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.

17. Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.

Ka pipe ipin Lúùkù 2