Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 2:33-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Ẹnu sì ya Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.

34. Síméónì sì súre fún wọn, ó sì wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Ísírẹ́lì; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí;

35. (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”

36. Ẹnìkan sì ń bẹ, Ánà wòlíì, ọmọbìnrin Fánúénì, ní ẹ̀yà Ásérì: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúndíá rẹ̀ wá;

37. Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹ́ḿpílì, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru.

38. Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerúsálémù.

39. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Gálílì, sí Násárẹ́tì ìlú wọn.

40. Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.

41. Àwọn òbi rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerúsálémù ní ọdọọdún sí Àjọ-ìrékọjá.

42. Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerúsálémù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà.

43. Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jésù dúró lẹ́yìn ní Jerúsálémù; Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.

44. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn.

45. Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerúsálémù, wọ́n ń wá a kiri.

46. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹ́ḿpílì ó jòkòó ní àárin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ti wọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè.

47. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 2