Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 2:31-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;

32. Ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,Àti ògo Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.”

33. Ẹnu sì ya Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.

34. Síméónì sì súre fún wọn, ó sì wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Ísírẹ́lì; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí;

Ka pipe ipin Lúùkù 2